Matiu 24:43-44
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
43 Ṣùgbọ́n, kí ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí náà tí olè yóò wá, ìbá máa ṣọ́nà, òun kì bá ti jẹ́ kí a já wọ ilé rẹ̀. 44 Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní wákàtí àìròtẹ́lẹ̀ ni dídé Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́.
Read full chapter
1 Tẹsalonika 5:2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 (A)nítorí ẹ̀yin pàápàá mọ̀ wí pé ọjọ́ Olúwa yóò wá bí olè lóru.
Read full chapter
Ìfihàn 3:3
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
3 Nítorí náà rántí bí ìwọ ti gbà, àti bí ìwọ ti gbọ́, kí o sì pa á mọ́, kí o sì ronúpìwàdà. Ǹjẹ́, bí ìwọ kò ba ṣọ́ra, èmi yóò dé sí ọ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ́ wákàtí tí èmi yóò dé sí ọ.
Read full chapter
Ìfihàn 16:15
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
15 (A)“Kíyèsi i; ń bọ̀ bi olè, ìbùkún ni fún ẹni tí ń ṣọ́nà, tí ó sì ń pa aṣọ rẹ̀ mọ́, kí ó má bá a rìn ni ìhòhò, wọn a sì rí ìtìjú rẹ̀.”
Read full chapter
2 Peteru 3:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 Ṣùgbọ́n ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá bí olè ní òru; nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo ńlá, àti àwọn ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́, ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ó wà nínú rẹ̀ yóò sì jóná túútúú.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.