Add parallel Print Page Options

Jesu fi ara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀

36 (A)Bí wọ́n sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí Jesu tìkára rẹ̀ dúró láàrín wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.”

37 Ṣùgbọ́n àyà fò wọ́n, wọ́n sì wárìrì, wọ́n ṣe bí àwọn rí ẹ̀mí kan. 38 Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ara yín kò lélẹ̀? Èé sì ti ṣe tí èròkerò fi ń sọ nínú ọkàn yín? 39 (B)Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, pé èmi tìkára mi ni! Ẹ dì mímú kí ẹ wò ó nítorí tí iwin kò ní ẹran àti egungun lára, bí ẹ̀yin ti rí tí èmi ní.”

Read full chapter