Eksodu 32:32
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
32 (A)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n ṣùgbọ́n tí kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, pa orúkọ mi rẹ́ kúrò nínú ìwé tí ìwọ ti kọ.”
Read full chapter
Saamu 69:28
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
28 (A)Jẹ́ kí a yọ wọ́n kúrò nínú ìwé ìyè
kí á má kà wọ́n pẹ̀lú àwọn olódodo.
Daniẹli 12:1
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìgbà ìkẹyìn
12 (A)“Ní àkókò náà, ni Mikaeli, ọmọ-aládé ńlá, ẹni tí o ń dáàbò bo àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò dìde. Àkókò ìpọ́njú yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè títí di àkókò náà. Ṣùgbọ́n ní àkókò náà àwọn ènìyàn rẹ̀, gbogbo àwọn tí a bá ti rí orúkọ wọn nínú ìwé ni a ó gbàlà.
Read full chapter
Filipi 4:3
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
3 (A)Mo sì bẹ̀ yin pẹ̀lú bí alájọru àjàgà mi tòótọ́, ran àwọn obìnrin wọ̀nyí lọ́wọ́, nítorí wọn bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìfẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́ nínú ìhìnrere, àti Klementi pẹ̀lú, àti àwọn olùbáṣiṣẹ́ mi yòókù pẹ̀lú, orúkọ àwọn tí ń bẹ nínú ìwé ìyè.
Read full chapter
Heberu 12:23
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
23 Si àjọ ńlá tí ìjọ àkọ́bí tí a ti kọ orúkọ wọn ni ọ̀run, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run onídàájọ́ gbogbo ènìyàn, àti sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀mí olóòtítọ́ ènìyàn tí a ṣe ni àṣepé, o
Read full chapter
Ìfihàn 3:5
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
5 (A)Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, òun náà ni a ó fi aṣọ funfun wọ̀; èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi, àti níwájú àwọn angẹli rẹ̀.
Read full chapter
Ìfihàn 13:8
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
8 Gbogbo àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì máa sìn ín, olúkúlùkù ẹni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀, sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-Àgùntàn tí a tí pa láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.
Read full chapter
Ìfihàn 21:27
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
27 (A)Ohun aláìmọ́ kan ki yóò sì wọ inú rẹ̀ rárá, tàbí ohun tí ń ṣiṣẹ́ ìríra àti èké; bí kò ṣe àwọn tí a kọ sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-àgùntàn.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.