1 Ọba 10:1-10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ayaba Ṣeba bẹ Solomoni wò
10 (A)Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ òkìkí Solomoni àti ì bà ṣe pọ̀ rẹ̀ ní ti orúkọ Olúwa, ó sì wá láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè líle. 2 Ó sì wá sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńláńlá, pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀. 3 Solomoni sì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyí tí ó ṣòro fún ọba láti ṣàlàyé fún un. 4 Nígbà tí ayaba Ṣeba sì rí gbogbo ọgbọ́n Solomoni àti ààfin tí ó ti kọ́. 5 Oúnjẹ tí ó wà lórí i tábìlì rẹ̀, ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti ìdúró àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀, àti ẹbọ sísun tí ó sun ní ilé Olúwa, kò sì sí ẹ̀mí kan nínú rẹ̀ mọ́!
6 Ó sì wí fún ọba pé, “Òtítọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní orílẹ̀-èdè mi ní ti iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ. 7 Ṣùgbọ́n èmi kò sì gba nǹkan wọ̀nyí gbọ́ títí ìgbà tí mo wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Sì kíyèsi i, a kò sọ ìdajì wọn fún mi; ìwọ sì ti fi ọgbọ́n àti ìrora kọjá òkìkí tí mo gbọ́. 8 Báwo ni inú àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe dùn tó! Báwo ni inú dídùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n sì ń gbọ́ ọgbọ́n rẹ! 9 Ìbùkún ni fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó ní inú dídùn sí ọ, tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ Israẹli. Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn Israẹli títí láé, ni ó ṣe fi ọ́ jẹ ọba, láti ṣe ìdájọ́ àti òdodo.”
10 Ó sì fún ọba ní ọgọ́fà (120) tálẹ́ǹtì wúrà, tùràrí olóòórùn dídùn lọ́pọ̀lọpọ̀, àti òkúta iyebíye. Kò sí irú ọ̀pọ̀lọpọ̀ tùràrí tí a mú wá tí ó dàbí irú èyí tí ayaba Ṣeba fi fún Solomoni ọba.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.