Add parallel Print Page Options

12 (A)Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹfà mo sì rí i, sì kíyèsi i, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá kan ṣẹ̀; oòrùn sì dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀ onírun, òṣùpá sì dàbí ẹ̀jẹ̀; 13 (B)àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run sì ṣubú sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń rẹ̀ àìgbó èso rẹ̀ dànù, nígbà tí ẹ̀fúùfù ńlá bá mì í.

Read full chapter

10 (A)Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti ìkójọpọ̀ wọn
    kò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn.
Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn yóò di òkùnkùn
    àti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn.

Read full chapter

10 (A)Ayé yóò mì níwájú wọn;
    àwọn ọ̀run yóò wárìrì;
oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn,
    àwọn ìràwọ̀ yóò sì fà ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn.

Read full chapter

15 Ọjọ́ náà yóò jẹ́ ọjọ́ ìbínú,
    ọjọ́ ìrora àti ìpọ́njú,
ọjọ́ òfò àti idà ọjọ́ ìdahoro
    ọjọ́ òkùnkùn àti ìtẹ̀ba,
    ọjọ́ kurukuru àti òkùnkùn biribiri,

Read full chapter